Jump to content

Andy Dick

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Andy Dick (2012)

Andrew Roane Dick (tí wọ́n bí pẹ̀lú orúkọ Andrew Thomlinson, ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1965) jẹ́ òṣèré àti apanilẹ́rìn-ín ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.[1] Wọ́n bí Dick ní Charleston, South Carolina,, ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré ìtàgé The Second City, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa eré ìtàgé àdánidá (improvisational theatre). Dick ti pẹ́, ó sì ti ṣe iṣẹ́ àṣeyọrí nínú iṣẹ́ adẹ́rìn-ín-pòṣónú. Ó ti ṣe eré apanilẹ́rìn-ín ní onírúurú Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ti ṣe àgbéjáde ọ̀pọ̀ àwo orin apanilẹ́rìn-ín, ó sì ti kópa nínú ọ̀pọ̀ eré orí tẹlifíṣọ̀nù àti fíìmù. Iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ tó jẹ́ ti eré orí tẹlifíṣọ̀nù déédéé ni èyí tó ṣe nínú eré The Ben Stiller Show, èyí tí ilé-iṣẹ́ Fox gbé jáde láàárín ọdún 1990 sí 1999, ó máa ń farahàn déédéé nínú eré NewsRadio tí ilé-iṣẹ́ NBC gbé jáde, ó sì tún kó ipa gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-òṣèré nínú eré Less than Perfect. Ó tún ń ṣe eré méjì tí kò gbani lákòókò ní orí tẹlifíṣọ̀nù ní ilé-iṣẹ́ MTV. Àwọn eré náà ni eré apanilẹ́rìn-ín onírúurú àwòrán tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Andy Dick Show(2001), àti eré ìfihàn ìgbésí ayé gidi tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Assistant (2004). Bákan náà, a tún mọ̀ ọ́n mọ àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ ní onírúurú ìgbà nínú àwọn ètò apanilẹ́rìn-ín Comedy Central Roasts.

A tún mọ Andrew Dick sí ẹni tó ní àwọn ìwà ìbàjẹ́ lọ́wọ́, ó ní ìṣòro nipa ìgbẹ́kẹ̀lé oògùn olóró, wọ́n sì ti fi ẹ̀sùn ìwà ìbálòpọ̀ tí kò bófin mu kàn án. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọlọ́pàá ti mú un.[2][3]. Dick sọ pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún ni òun ti ń sapá láti borí ìṣòro lílo oògùn olóró àti ọtí àmupara. Ní ọdún 2025, ó ṣàlàyé pé òun ti gba ìtọ́jú àkànṣe láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró ní ìgbà mẹ́tàdínlógójì. Ní ọdún 2022, wọ́n dá a lẹ́bi nítorí ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ṣẹ̀ ní ọdún 2018, ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ti dá lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀. [4][5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ìgbésíayé àti Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Andy Dick ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1965,[6] ní ìlú Charleston South Carolina, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì sọ ọ́ ní Andrew Thomlinson. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bí i, Allen àti Sue Dick gba á tọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ,wọ́n sì sọ orúkọ rẹ̀ di Andrew Roane Dick. Wọ́n tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹlẹ́sìn Presbyterian.[7] Bàbá rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. [8]

Gégébí ọmọ kékeré, Dick gbé pẹ̀lú àwọn òbí rè ní ìlú Connecticut, Pennsylvania, New York, àti Yugoslavia kí ó tó kó lọ sí Chicago ní ọdún 1979.[9] Ó lọ sí ilé èkó gíga George Walton Comprehensive High School ní Cobb County, Georgia.[10] Dick kópa nínú àwọn eré orí ìtàgé lórísirísi ni àkókò tí ó wà ní ilé èkó gíga, tí wọ́n sì yàn sí oyè ọba láàrín àwọn akẹ́kọ homecoming king ní àkókò ọdún 1983 ní ìgbà tí ó wà ní ìpele àgbà ní ilé èkó òún. Ó parí ní ilé èkó Joliet West High School tí ó wà ní Joliet, Illinois, ní ọdún 1984.[11]

Ní àkókò ìgbà tí ó wà ní ilé èkó gíga, Dick lọ orúkọ bàbá rè gẹ́gẹ́bi àpárá láàrin àwọn akegbé re; ní ojó kan, Dick wo aṣọ ẹ̀yà àwọn ọṣèré alágbára orí ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, tí ó sì pe ara rẹ̀ ní "Super Dick".[12] Anthony Rapp jẹ́ òré Dick láti ìgbà èwe won.[13]

Lẹ́yìn tí ó jáde ilé ìwé, Dick darapọ̀ mọ́ àwọn eléré ìtàgé tí wọ́n fi ìkàlè sí Chicago tí orúkọ wọn ń jẹ́ The Second City tí ó si tún lọ sí Yunifásítì ti Illinois Wesleyan University fún sáà kan kí ó tó darapọ̀ mọ́ ìlé ẹ̀kọ́ Columbia College Chicago, níbi tí ó ti lọ òpò àkókò rẹ̀ bí akẹ́kọ,[14][8] tí òun kò ẹ̀kọ́ nípa ìmò eré orí ìtàgé àpilẹ̀kọ lórí, improvisational theater (improv) nípa eré àwàdà ni yàrá ìtàgé iO Theater.

Iṣẹ́ ìṣe Rè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní orí ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Dick holding a piñata with a cutout of Tom Green for The 1 Second Film in December 2004

Andy Dick bèrè eré àwàdà rẹ lórí èrò àmóhùnmáwòrán gẹ́gẹ́bi òkan lára Àwọn Òṣìṣẹ́ Lẹ́yìn Kámẹ́rà níbi eré aláwàdà sketch comedy The Ben Stiller Show, tí wọ́n bèrè sí ń gbé jáde lórí ìkànnì Fox Network nínú oṣù òwéwè ọdún 1992 titi di oṣù ògún ní ọdún 1995.[15] Ní ọdún 1993, ní alẹ́ ọjọ́ kẹèta ètò tuntun tí David Letterman ṣe ní orí ìkànnì CBS, Dick ṣe ìfarahàn gẹ́gẹ́bi "Donnie the CBS Page Who Likes to Suck Up", tí ó fún Letterman ní ago. Lẹ́yìn na ni Letterman fún Dick ní gègé-ìkọ̀wé, lèyí tí ó mú kí Dick bù sí ẹkún gba ẹyin Ìyàrá Ìmúra àwọn Òṣèré kọjá.[16]

Ní ọdún 1994, Dick kópa gẹ́gẹ́bi Onídìrí tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Pepé nínú àkọ́lé erée The Nanny abala ti "Maggie the Model".[citation needed] ó tún kópa gẹ́gẹ́bi Zachary Smart, Eni ti o jẹ ọmọkùnrin fún ọṣèré tí ó ṣe Maxwell Smart àti gẹ́gẹ́bi Agent 99, nínu eré Get Smart (1995),ní èyí tí ó jẹ́ Ẹ̀dá-ìtàn tí ó gbìyànjú láti yẹra fún lójúnà áti lè ṣiṣẹ́ lórí èrò Àsọ̀rọ̀mágbèsì NewsRadio.[17] ni Ọdún 2001, Dick kópa pẹ̀lú Kieran Culkin Lori eré kúkúrú kan tí wọ́n ṣe lórí èrò àmóhùnmáwòrán tí NBC Go Fish.[18]

Dick ṣe àfihàn lórísirísi lórí òpò àwọn Eré Awada Atìgbàdégbà áti àwọn Eré Onípele, bí NewsRadio lórí ìkànnì NBC (1995–1999), níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́bi ọníròyìn Matthew Brock, àti ní orí eré aláwàdà tí ìkànnì ABC tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Less than Perfect gẹ́gẹ́bi Owen Kronsky.[19]

Ní ọdún 2001, Dick, pẹ̀lú àwọn akegbé rẹ̀ àti Olùgbéjáde eré dìjo se The Andy Dick Show fún ìkànnì MTV tí ó wá sí òpin ní ọdún 2003 lẹ́yìn ipele eré mẹ́ta.[citation needed] ni Ọdún 2004, Dick kópa nínú Eré Onípele Amóhùnmáwòrán Alápara The Assistant, ní orí ìkànnì MTV lèyí tí ó dá àpárá pẹ̀lú àwọn Àwọn Abá Eré láti inú erée The Apprentice, The Bachelor, Queer Eye for the Straight Guy, àti Survivor.[citation needed]

Dick ṣe àfihàn gẹ́gẹ́bi Àlejò Pàtàkì nínú Eré Star Trek: Voyager níbi tí ó ti kópa bí Emergency Medical Hologram Mark II ní "Message in a Bottle".[citation needed] ó kópa nínú ipele ṣáá Kẹ̀wá nínú ìdíje ti Celebrity Poker Showdown, níbi tí ó ti gbé ipò tí ó kẹ́yìn tí Robin Tunney, Christopher Meloni, Macy Gray, àti Joy Behar sì síwájú rẹ̀.[citation needed]

Ní ọdún 2008, Dick ṣe àfihàn nínú ìpele kẹta nínú eré The Real World: Hollywood láti sọ fún àwọn Òṣèré pé wọ́n yíò má kò ẹ̀kọ́ àtúnṣe nínú ilé ẹ̀kọ́.[20][21]

Dick jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n díje nínú eré Season 16 of Dancing with the Stars ní ọdún 2013.[22] Wọ́n pín pẹ̀lú Ọmọ Ẹgbẹ́ Òṣèré télèri Sharna Burgess tí wọ́n sí wà ní ipò keèje nínú ìdíje na. Dick ṣe àfihàn lórí eré ìkànnì ABC's Celebrity Wife Swap ni ọjọ kẹrìnlá Oṣu keje, ọdún 2013.[23]

Eré orí àmóhùnmáwòrán

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọkan lára àwọn eré àgbéléwò tí Andy Dick kópa nínú rẹ ni ibere ìṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré je eré Àròko tí ó dà lórí Andy fún ra rẹ̀ tí wọ́n so di eré fídíò tí orúkọ rẹ jẹ́ Double Dragon.[citation needed] In 1993, Dick played himself in the mockumentary The Making of... And God Spoke.[citation needed] ó tún kópa gẹ́gẹ́bí ọṣèré pẹ̀lú aláwàdà Pauly Shore níbi eré aláwàdà aláfiwé ogun tí ọdún 1994, In the Army Now.[citation needed] bákannáà, ní ọdún 1994, Dick ṣe ìfarahàn rán pé ní àkókò eré tí Ben Stiller yio darí, Reality Bites.[citation needed]

Ní ọdún 1997, Dick kópa nínú eré Bongwater pẹ̀lú Luke Wilson àti Jack Black gẹ́gẹ́bí ọ̀rẹ́ Wilson's tí ó jẹ́ Alábàjíkà tí ó fún ní ilé láti má gbé lẹ́yìn tí iná jó ilé rè.[24] ni Ọdún 1999, Dick kópa gẹ́gẹ́bi òkan lára àwọn òṣìṣẹ́ Dr. Claw's nínú eré Inspector Gadget.[citation needed]

Ní ọdún 2000, Dick ṣe àfihàn rán pé( cameo appearance) nínú eré Dude, Where's My Car?. Nínú ọdún na bákannáà, ó farahàn Gégébí akọ̀wé ilé ìtura nínú eré aláwàdà àwọn ọ̀dọ́, Road Trip. Ní ọdún 2001, Dick ṣe àfihàn rán pé gẹ́gẹ́bí Olga tí ń báni fi ọwọ́ wó ara nínú eré aláwàdà láti ọwọ́ Ben Stiller Pẹ̀lú àkọ́lé Zoolander.[citation needed]

Ní ọdún 2002, Dick ṣe àfihàn gẹ́gẹ́bí awàkò taxi nínú fíìmù orin àwọn ẹgbẹ́ Ash's music video "Envy".[25] ni ọdún 2003, ó ṣe àfihàn nínú eré Will Ferrell Pẹ̀lú àkọlé Old School gẹ́gẹ́bí Barry, olùkọ́ni nípa ìmò ìbálòpò pẹ̀lú ẹnu àti gẹ́gẹ́bí Santa burúkú nínú eré The Hebrew Hammer.[citation needed] ní ọdún 2005, wọ́n ṣe àfihàn Dick nínú àkásílè eré ìtàn ìgbésí ayé ẹni pẹ̀lú àkọlé The Aristocrats. Ní ọdún 2006, ó ṣe àfihàn ninu eré Employee of the Month gẹ́gẹ́bí Lon, onímọ̀ nípa àwò ojú tí ojú ń dùn.[26] òun ni ó tún fi ohùn rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí Mambo nínú erée Happily N'Ever After (2007) àti ohùn Boingo nínú eré Hoodwinked! (2005).[citation needed]

Àkókó eré àgbéléwò tí Dick's yio kópa nínú rẹ gẹ́gẹ́bí olùdarí ni Danny Roane: First Time Directortí ó jáde ní ọdún 2006. Ní owó ìparí oṣù opé ni ọdún 2008, Dick filéde lórí ojú òpó rẹ̀ wípe ní òun ti parí kíkọ ìwé fún eré fíìmù rẹ̀ tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Daphne Aguilera: Get into It, lèyí tí Daphne Aguilera kópa gẹ́gẹ́bí èmí ìwà kejì Dick.[27]

  1. ↑ Ogunnaike, Lola (June 30, 2003). "No Mealworm Snacks for Late-Night Comic". The New York Times. https://www.nytimes.com/2003/06/30/arts/no-mealworm-snacks-for-late-night-comic.html.
  2. ↑ "Comedian Andy Dick Faces Sexual Harassment Allegations". NBC Los Angeles. July 2, 2018. https://www.nbclosangeles.com/news/local/Comedian-Andy-Dick-Faces-Sexual-Harassment-Allegations-487142621.html.
  3. ↑ Desta, Yohana (October 31, 2017). "Andy Dick Dropped from Film Amid Latest Sexual Harassment Claims". Vanity Fair. https://www.vanityfair.com/hollywood/2017/10/andy-dick-fired-sexual-harassment-claims. Retrieved October 12, 2018.
  4. ↑ Stelloh, Tim (January 14, 2023). "Comedian Andy Dick accused of public intoxication, failing to register as a sex offender". NBC News. Archived from the original on March 11, 2023. Retrieved October 31, 2023. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. ↑ Travis, Emlyn (January 13, 2023). "Andy Dick arrested and charged with public intoxication, failing to register as sex offender". Entertainment Weekly. https://ew.com/celebrity/andy-dick-arrested-charged-public-intoxication-failing-to-register-as-sex-offender/. Retrieved March 24, 2023.
  6. ↑ "Andy Dick: Movies, Photos, Videos, News, Biography & Birthday | Times of India". The Times of India (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2025-09-25.
  7. ↑ Lawson, Steven (May 2003). "Andy Dick Finds God the Hard Way". Beliefnet.com. Archived from the original on September 22, 2010. Retrieved November 20, 2010. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. 1 2 O'Brien, Ken (December 13, 1998). "Humor in the Extreme". Chicago Tribune. https://www.chicagotribune.com/1998/12/13/humor-in-the-extreme/.
  9. ↑ Crisafulli, Chuck (July 26, 1997). "What's the Frequency, Andy?". Los Angeles Times. https://www.latimes.com/archives/la-xpm-1997-jul-26-ca-16285-story.html.
  10. ↑ Brasch, Ben (March 2, 2018). "Here are some of the most famous folks connected to Cobb". The Atlanta Journal-Constitution. Archived from the original on November 11, 2020. Retrieved November 14, 2024.
  11. ↑ "Andy Dick". Biography.com. Archived from the original on June 10, 2013.
  12. ↑ Guerrero, Lucio (June 4, 2006). "The Chicago Connection: They're ours – a surprising look at celebs' ties to the Windy City". Chicago Sun-Times. http://nl.newsbank.com/nl-search/we/Archives?p_product=CSTB&p_theme=cstb&p_action=search&p_maxdocs=200&p_topdoc=1&p_text_direct-0=1120AF3DD7E5A918&p_field_direct-0=document_id&p_perpage=10&p_sort=YMD_date:D&s_trackval=GooglePM.
  13. ↑ Wiegand, David (February 21, 2006). "From musical to memoir, actor Anthony Rapp comes up with dramatic making-of 'Rent' story and moving personal one". The San Francisco Chronicle. https://www.sfgate.com/entertainment/article/from-musical-to-memoir-actor-anthony-rapp-comes-2503727.php.
  14. ↑ "Did You Know?". Illinois Wesleyan University. Archived from the original on November 24, 2010. Retrieved November 20, 2010. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  15. ↑ "The Ben Still Show". IMDB. Archived from the original on April 21, 2025. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. ↑ wp-hikari (December 28, 2024). "Andy Dick Interview". Hikari Takano Interviews. Archived from the original on March 23, 2025. Retrieved March 23, 2025. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  17. ↑ Schimkowsitz, Matt (July 29, 2013). "Andy Dick in a 'Get Smart' Remake? What Could Go Wrong?". Vulture. Archived from the original on October 31, 2023. Retrieved July 7, 2021. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. ↑ Gallo, Phil (2001-06-18). "Go Fish". Variety (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2026-09-10.
  19. ↑ "Sara Rue, Andy Dick, Eric Roberts, Sherri Shepherd, Andrea Parker, Zach Levi & Will SassoABC’s “Less Than Perfect” Ensemble Q&A – SAG-AFTRA Foundation" (in en-US). SAG-AFTRA Foundation. https://sagaftra.foundation/programs/514/.
  20. ↑ "Video of Episode 3". The Real World: Hollywood. MTV. Archived from the original on May 5, 2008. Retrieved May 23, 2017.
  21. ↑ "Summary page for Episode 3 of The Real World: Hollywood". MTV. Archived from the original on May 29, 2009.
  22. ↑ Coyne, Kate; Shira, Dahvi (May 21, 2014). "Former DWTS Contestant Andy Dick Escorted from Ballroom During Finale". https://people.com/tv/former-dwts-contestant-andy-dick-escorted-from-ballroom-during-finale/.
  23. ↑ Raftery, Liz (July 12, 2013). "Celebrity Wife Swap Sneak Peek: Andy Dick and Lorenzo Lamas Trade Off". TV Guide. Archived from the original on July 9, 2021. Retrieved July 7, 2021. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  24. ↑ Horton, Jay (April 18, 2017). "The Story Behind Bongwater: Portland's Lost Stoner Comedy Starring Luke Wilson, Jack Black and Brittany Murphy". Willamette Week. Archived from the original on July 9, 2021. Retrieved July 7, 2021. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  25. ↑ "Release group "Envy" by Ash - MusicBrainz". musicbrainz.org. Retrieved 2025-09-25.
  26. ↑ Bilington, Alex (October 5, 2006). "Exclusive: Andy Dick Chats About Employee of the Month". FirstShowing. Archived from the original on July 9, 2021. Retrieved July 7, 2021. Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  27. ↑ "Andy Dick confirms Daphne Aguilera movie". Archived from the original on July 7, 2011.